YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

A KI YIN KAABO SI IKAANI YORUBA BROADCASTING NETWORK(YBN)
AWON ETO WA:
AGBEYEWO IROYIN
ORO TO'NLO
AJAABALE IROYIN
IROYIN LEREFE
ATI AWON ETO LOLOKAN O JOKAN


YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KỌKÀNLÁ OṢÙ KẸ́JỌ ỌDÚN 2025

1. ÀWỌN ADARÍ ÌGBÌMỌ̀ ILÉ IṢẸ́ OLÚṢẸ́GUN ỌBÁSANJỌ́ PRESIDENTIAL LIBRARY (OOPL) TÓ WÀ NÍ ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA TI FẸ̀SÙN KAN ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÌWÀ ÌBÀJẸ́ ÀTI ṢÍṢE OWÓ ÌLÚ KÚMỌKÙMỌ́ LÓRÍ BÍ WỌ́N ṢE YABO ỌGBÀ ILÉ IṢẸ́ NÁÀ LỌ́NÀ TÍ Ò BÓFIN MU LÁÁRỌ̀ KÙTÙKÙTÙ ỌJỌ́ ÀÌKÚ ÀNÁ LÁTI DABARÚ AYẸYẸ KÀN TÍ ÀWỌN KÀN Ń ṢE NÍBẸ̀

2. ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ AFRICAN DEMOCRATIC CONGRESS(ADC) NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS TI Ń DUNNÚ KÌRI PÉ ÀWỌN TI NÍ ẸGBẸ̀RÚN LỌ́NÀ ẸGBẸ̀RIN ÈNÌYÀN NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ

3. WỌ́N TI SỌ ṢẸ́GUN ÒGÚNDÍPẸ̀ ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, ỌMỌ ỌDÚN MẸ́TÀLÉLỌ́GBỌ̀N TÓ WÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ GẸ̀Ẹ́SÌ SÍ Ẹ̀WỌ̀N ỌDÚN MÁRÙN-ÚN LÓRÍ Ẹ̀SÙN ÌFIBÁBÁNILÒPỌ̀ ÀTI NÍNA ỌWỌ́ ÌBÁLÒPỌ̀ SÍ OBÌNRIN KÀN LỌ́NÀ ÀÌTỌ́

4. ÌGBÌMỌ̀ ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN AGÙNBÁNIRỌ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NYSC) TI SỌ PÉ ÀWỌN Ò MÚ ÌWÉ Ẹ̀RÍ SÍNSÌNRÚ ÌLÚ USHIE RITA UGUAMAYE DÁNÍ LÁTARI PÉ Ó SỌ̀RỌ̀ LÒDÌ SÍ ÌṢÈJỌBA ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ

5. ÌGBÌMỌ̀ ADARÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA ỌBÁFẸ́MI AWÓLỌ́WỌ̀ TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA FÚN ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ LÁTI TÈTÈ BÁ WỌN ṢÀWÁRÍ AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ NÁÀ DORCAS OSEGHALE TÍ WỌ́N Ń WÁ LẸ́YÌN TÓ SỌ FÚN ÀWỌN Ọ̀RẸ́ Ẹ̀ PÉ ÒUN FẸ́ LỌ RA OÚNJẸ NÍ ABÚLÉ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÓ WÀ NÍ ÒPÓPÓNÀ ẸDẸ

6. ÀWỌN ÈNÌYÀN TÓ TÓ ẸGBẸ̀RÚN MẸ́RIN TÍ Ẹ̀KÚN OMI ṢE LỌ́ṢẸ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ADAMAWA TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA PÉ OÚNJẸ ÌRÀNWỌ́ TÍ WỌ́N PÍN FÚN WỌN ÈYÍ TÍ IGBÁKEJÌ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ ÌYẸN Ọ̀JỌ̀GBỌ́N KALETAPWA FARAUTA JẸ́ ALÁGA FÚN JẸ́ ÀWỌN OÚNJẸ TÍ ỌJỌ́ TI LỌ LÓRÍ WỌN

7. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ, BÍỌ́DÚN OYÈBÁNJÍ TI GBA IṢẸ́ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀTÀWỌN OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN PÀTÀKÌ Ẹ̀ KAN TÍ WỌ́N WÀ NÍNÚ ÌGBÌMỌ̀ ÌṢÈJỌBA Ẹ̀

8. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÉ SÍ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI MÁA RA ÀWỌN ǸKAN TÍ WỌ́N Ń ṢE LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ

9. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN TI KÉDE LỌ́JỌ́ ÀÌKÚ ÀNÁ ÈRÒǸGBÁ Ẹ̀ LÁTI GBIN IGI MÍLÍỌ́NÙ KAN SÍ ÀÁDỌ́TA SAARE ILẸ̀ NÍTORÍ ÀTI DẸ́RÁN IPA BÚBURÚ TÍ ÀYÍPADÀ OJÚ ỌJỌ́ Ń KÓ NÍPÌNLẸ́ ÒGÙN

10. ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ TÍ WỌ́N TÓ IGBA YABO ÌLÚ KAN LÓRU NÍ ÌPÍNLẸ̀ KWARA, WỌ́N SÌ ṢEKÚ PA ÀWỌN ÈNÌYÀN MÁRÙN-ÚN LÉYÌÍ TÍ ỌLỌ́PÀÁ KAN WÀ NÍNÚ WỌN

OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ (GLAMOURLADY)

LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN)

6 months ago | [YT] | 4

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸSÀN-ÁN OṢÙ KẸ́JỌ ỌDÚN 2025

1. ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ ÈTÒ ÌDÁNWÒ WAEC TI TARI ÈSÌ ÌDÁNWÒ ỌDÚN 2025 SÍTA PADÀ LÉYÌÍ TÍ ÀWỌN TÓ YEGE TI FÒ FẸ̀RẸ̀ SÓKÈ LÁTI ÌDÁ MÉJÌDÍNLÓGÓJÌ ÀTI DÍẸ̀ TÓ WÀ TẸ́LẸ̀ SÍ ÌDÁ MÉJÌLÉLỌ́GỌ́TA ÀTI DÍẸ̀

2. ÀGBARÍJỌPỌ̀ ÀWỌN ẸGBẸ́ ÀWÙJỌ KÀN TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀWỌN LÒDÌ SÍ BÍ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢE FẸ́ GBÉ OWÓ TÓ TÓ BÍLÍỌ́NÙ LỌ́NÀ OKÒÓÓLẸ́Ẹ̀DẸ́GBẸ̀RIN Ó DÍN MẸ́JỌ NÁÍRÀ SÍLẸ̀ FÚN ÀTÚNṢE ÈBÚTÉ KÌNNÍ PÁPÁKỌ̀ ÒFURUFÚ MÚRÍTÀLÁ MÙHÁMMED LÉYÌÍ TÓ JẸ́ PÉ EBI Ọ̀PÀGBÀ FỌWỌ́ MẸ́KẸ́ Ń PA Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

3. ÀWỌN ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń PÈSÈ ÀWỌN ǸKAN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÀDÁNÙ OWÓ TÓ TÓ TÍRÍLÍỌ́NÙ KAN ÀTI IGBA NÁÍRÀ LÁÀRIN ỌDÚN 2019 SÍ 2023 LÁTARI ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ MÁNIGBÀGBÉ TÓ ṢẸLẸ̀ LÁWỌN ỌDÚN YÌÍ LÉYÌÍ TÓ SÌ JẸ́ PÉ ǸKAN TÍ Ń ṢẸNU IRE FÚN WỌN LÁSÌKÒ ÌṢÈJỌBA ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ BÁYÌÍ

4. ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ AFRICAN DEMOCRATIC CONGRESS (ADC) TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ Ò LÈ SỌ PÉ ÒUN WÀ LÓRÍ ÌJỌBA PẸ̀LÚ BÍ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ ṢE Ń GBA OWÓ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÀGBẸ̀ KÍ WỌ́N TÓ LÈ LỌ SÍNÚ OKO WỌN

5. ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA TI SỌ PÉ ÀWỌN NÍ KÍ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ó KÚRÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ ÀWỌN NÍTORÍ ÀWỌN ÌWÀ JÌBÌTÌ ÀTI ÌWÀ BÚBURÚ TÓ KÚN ỌWỌ́ WỌN

6. WỌ́N TI ṢE Ẹ̀YẸ ÌKẸYÌN ÀTI ÈTÒ ÌSÌNKÚ FÚN OLÚBÀDÀN TI ÌLÚ ÌBÀDÀN, ỌBA OWÓLABÍ ỌLÁKÙLẸ́YÌN NÍ ÌJỌ SAINT PETER'S CATHEDRAL TÓ WÀ NÍ ARẸMỌ NÍ ÌLÚ ÌBÀDÀN

7. ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÌWÀ ÌBÀJẸ́ ÀTI ÌṢOWÓ ÌLÚ KÚMỌKÙMỌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (EFCC) TI NAWỌ́ GÁN ÀWỌN ALUJIBITI ORÍ Ẹ̀RỌ AYÉLUJÁRA MẸ́RÌNDÍNLÁÀDỌ́RIN NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN ÀTI ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ

8. ÀGBARÍJỌPỌ̀ ẸGBẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ PÁPÁKỌ̀ ÒFURUFÚ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI WỌ́N Ń GBÈRÒ ÀTI BẸ̀RẸ̀ ÌYANṢẸ́LÓDÌ LÁTI ỌJỌ́ AJÉ TI FAGILÉ ÌYANṢẸ́LÓDÌ WỌN LẸ́YÌN TÍ WỌ́N TI FI ỌWỌ́ SÍ ÌWÉ ÀJỌYÉPỌ̀ PẸ̀LÚ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ OWÓ OṢÙ

9. ALÁGA ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ ÈTÒ ÌDÌBÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (INEC), Ọ̀JỌ̀GBỌ́N MAHMOOD YÀKÚBÙ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÀJỌ NÁÀ TI Ń GBÉ ÌGBÉSẸ̀ LÁTI MÚ KÍ ÀWỌN ẸLẸ́WỌ̀N Ò NÍ ÀǸFÀÀNÍ LÁTI MÁA DÌBÒ LÁSÌKÒ ÈTÒ ÌDÌBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

10. ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ ṢORO BÍ AGBỌ́N NÍ ÌPÍNLẸ̀ PLATEAU, WỌ́N SÌ PA ÈNÌYÀN MẸ́TA PẸ̀LÚ ÒJÍṢẸ́ ỌLỌ́RUN KAN LỌ́JỌ́ ẸTÌ ÀNÁ

OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ (GLAMOURLADY)

LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN)

6 months ago | [YT] | 7

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸ́JỌ OṢÙ KẸ́JỌ ỌDÚN 2025

1. ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ AṢÍWÁJÚ BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI YAN ABDULLAHI GARBA RAMAT ỌMỌ ỌDÚN MỌ́KÀNDÍNLÓGÓJÌ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁGA ÀTI ADARÍ ÌGBÌMỌ̀ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

2. ÀJỌ́ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ OJÚ ỌJỌ́ ÀTI Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KÚN OMI TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ Ẹ̀KÚN OMI MÁA ṢẸLẸ̀ NÍ ÀWỌN ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ MÉJÌDÍNNÍGBA KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ MỌ́KÀNLÉLỌ́GBỌ̀N LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ BẸ̀RẸ̀ LÁTI ỌJỌ́ KÉJE SÍ ỌJỌ́ KỌKÀNLÉLÓGÚN OṢÙ KẸ́JỌ TÍ A WÀ YÌÍ

3. ÀWỌN ẸGBẸ́ ỌLỌ́SÌN ẸJA NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ (LASCAFAN) TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA FÚN ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ PÉ KÍ Ó GBÀ WỌ́N LÓRÍ BÍ Ọ̀GBÀRÁ ÒJÒ ṢE KÓ ÀWỌN ẸJA WỌ́N TÍ OWÓ Ẹ̀ TÓ ÀÁDỌ́JỌ MÍLÍỌ́NÙ NÁÍRÀ LỌ

4. AKỌ̀WÉ ÀPAPỌ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AṢÒFIN GEORGE AKUME TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA LÓRÍ BÍ ÀWỌN KÀN ṢE ṢE ÀRỌ́DÁRỌDÀ OHÙN Ẹ̀ LÁTI FI MÁA LU ÀWỌN ÈNÌYÀN NÍ JÌBÌTÌ PÉ ÒUN FẸ́ BÁ WỌN WÁ IṢẸ́

5. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI LÉ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ỌGBÀ ÀTÚNṢE MẸ́Ẹ̀DÓGÚN KÚRÒ LẸ́NU IṢẸ́, Ó SÌ GBÉ IPÒ ÀWỌN MỌ́KÀNDÍNLỌ́GỌ́TA WÁLẸ̀ SI LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ WỌ́N HU ÀWỌN ÌWÀ KÓTỌ́ KAN

6. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI FÒFIN DE OLÓRIN NÌ, WÀSÍÙ ÀYÌNDÉ MARSHAL TÍ GBOGBO ÈNÌYÀN MỌ̀ SÍ KWAM 1 PÉ KÒ GBỌDỌ̀ WỌ ỌKỌ̀ ÒFURUFÚ KANKAN FÚN OṢÙ MẸ́FÀ GBÁKO LÁTARI PÉ Ó HÙWÀ ÀÌTỌ́ NÍ PÁPÁKỌ̀ ÒFURUFÚ

7. ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÌLÚ Ẹ̀GBÁ GANGAN NI ÀDÌRẸ TÍ ṢẸ̀ WÁ, WỌ́N NÍ IRỌ́ ŃLÁ NI Ọ̀RỌ̀ TÍ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN, ADÉMỌ́LÁ ADÉLÉKÈ SỌ FÚN FẸ́MI GBÀJÀBÍÀMÍLÀ PÉ ÌLÚ ẸDẸ NÍ ÀWỌN ARÁ ÌLÚ Ẹ̀GBÁ TI JÍ BÍ WỌ́N ṢE Ń ṢE ÀDÌRẸ

8. ÀWỌN ÀGBẸ̀ TÓ WÀ NÍ AGBÈGBÈ DAN ISA NÍJỌBA ÌBÍLẸ̀ KAURA NAMODA NÍ ÌPÍNLẸ̀ ZAMFARA TI KÉ RORA JÁDE LÓRÍ BÍ WỌ́N ṢE SAN MÍLÍỌ̀NÙ KAN ÀTI ẸGBẸ̀TA NÁÍRÀ (#1.6m) FÚN ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ KÍ WỌ́N TÓ LÈ MÁA DÁKO BÍ WỌ́N ṢE FẸ́

9. BÀBÁLỌ́JÀ GBOGBOGBÒÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́, ÀLHÁJÌ YEKEEN ABASS TI PÀṢẸ PÉ KÍ GBOGBO ỌJÀ TÓ WÀ NÍ ÌLÚ ÌBÀDÀN Ó DI TÍTÌ PA LÁTARI ÌSÌNKÚ OLÚBÀDÀN TI ILẸ̀ ÌBÀDÀN, ỌBA OWÓLABÍ ỌLÁKÙLẸ́YÌN TÓ DI OLÓÒGBÉ

10. ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ Ẹ̀KA TI ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI NAWỌ́ GÁN OLÓYÈ KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ AJÍBÁDÉ LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ Ó FI TIPÁTIPÁ FÚN AFURASÍ OLÈ KAN TÓ Ń JÍ ÀGBÀDO NÍNÚ OKO RẸ̀ NÍ MÁJÈLÉ JẸ

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 5

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KEJE OṢÙ KẸ́JỌ ỌDÚN 2025

1. ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ AṢÍWÁJÚ BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI PÀṢẸ KÍ WỌ́N BẸ̀RẸ̀ SI NÍ SAN ÀFIKÚN OWÓ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TÓ TI FẸ̀YÌN TÌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LẸ́YÌN TÍ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ YÌÍ FẸ̀HỌ́NÚHÀN NÍ ÌLÚ ÀBÚJÁ

2. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ, BABÁJÍDÉ SANWÓ-OLÚ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÌṢÈJỌBA ÒUN TI ṢETÁN LÁTI FÌMỌ̀ṢỌ̀KAN PẸ̀LÚ ÌGBÌMỌ̀ ÀPAPỌ̀ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN TÍ WỌ́N Ń KÓ ṢÒWÒ ẸRÚ KIRI LÁTI WÁ OJÚTÙÚ SÍ MÍ MÁA KÓ ÀWỌN ÈNÌYÀN ṢÒWÒ ẸRÚ KIRI

3. ÀÀRẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, GOODLUCK EBELE JONATHAN TI Ń GBARADÌ LÁTI TÚN PADÀ DÍJEDUPÒ ÀÀRẸ LỌ́DÚN 2027 LÁTARI BÍ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) ṢE Ń RỌ̀Ọ́ LÁTI JẸ́ ỌMỌ OYÈ TÓ MÁA DÍJEDUPÒ ÀÀRẸ LÁTI INÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ

4. ADÁJỌ́ AJÀFẸ́TỌ̀ ỌMỌNÌYÀN NÌ, FẸ́MI FÁLÀNÀ TI SỌ ÒGÚLÙTU Ọ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀWỌN Ọ̀DARÀN ÀTÀWỌN ỌMỌ ÌGBORO NI WỌ́N GBA ÌṢÈJỌBA ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

5. ALÁGA ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÌWÀ ÌBÀJẸ́ ÀTI ṢÍṢE OWÓ ÌLÚ KÚMỌKÙMỌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (EFCC) ỌLÁ OLÚKÓYÈDÉ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÈYÍ TÓ PỌ̀JÙ NÍNÚ ÀWỌN ILÉ ÀTÀWỌN OUN ÌNÍ TÍ WỌ́N PA TÌ NÍ OLÚ ÌLÚ WA ÀBÚJÁ LÓ JẸ́ TÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ÌJỌBA TÍ WỌ́N KÓ OWÓ ÌLÚ JẸ LÁTI KỌ́ ÀWỌN ILÉ ÀWÒṢÍFÌLÀ NÁÀ


6. ÀWỌN ÒBÍ ÀTI ÀPAPỌ̀ ẸGBẸ́ ÀWỌN OLÙDÁSÍLẸ̀ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ALÁDÀNI GBOGBO (NAPPS) TI BẸNU ÀTẸ́ LU BÍ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÍ WỌ́N JÓKÒÓ ṢE ÌDÁNWÒ ÀṢÉKÁGBÁ ONÍWÈ MẸ́WÀÁ (WAEC) ṢE KÙNÀ ÌDÁNWÒ NÁÀ, WỌ́N BÉÈRÈ FÚN FÍFAGILÉ ÀWỌN ÌDÁNWÒ NÁÀ PÀÁPÀÁ JÙ LỌ ÈDÈ GẸ́Ẹ̀SÌ KÍ WỌ́N SÌ TÚN ÀWỌN ÌDÁNWÒ NÁÀ ṢE

7. ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AṢÍWÁJÚ BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ TI RAŃṢẸ́ ÌBÁNIKẸ́DÙN SÍ ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA, JOHN MAJAMA LÁTARI BÍ Ó ṢE PÀDÁNÙ ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ Ẹ̀ MÉJÌ ÀTÀWỌN MẸ́FÀ KAN SÍNÚ ÌJÀMBÁ ỌKỌ̀ ÒFURUFÚ

8. ALÁGA ÌGBÌMỌ̀ ADÉLÉ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) LẸ́KÙN ÌDÌBÒ APÁ GÚÚSÙ GÚÚSÙ, EMMANUEL ÒGIDÌ TI TÀKÒTÓ Ọ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÌGBÌMỌ̀ AMÚṢẸ́ṢE ÀPAPỌ̀ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ MÁA ṢE ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀWỌN ÌWÀ ÀTI ÌṢE ALÁKÒÓSO LÓLÚ ÌLÚ WA ÀBÚJÁ ÌYẸN NYESOM WIKE

9. OLÚWÒ TI ÌLÚ ÌWÓ, ỌBA ABDULROSHEED ÀKÀNBÍ ÀTÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ ÀGBÀÀGBÀ ILẸ̀ YORÙBÁ TI FÌMỌ̀ṢỌ̀KAN LÁTI ṢIṢẸ́ PAPỌ̀ LÁTI DÁ ÀÀBÒ BO ÀṢÀ YORÙBÁ KÍ WỌ́N SÌ ṢÀYẸ̀WÒ ÌPALÁRA TÍ ÀÌDÁ ÀÀBÒ BÓ ÀṢÀ YÌÍ MÁÀ Ń NÍ NÍLẸ̀ YORÙBÁ

10. ỌMỌ ILÉ IṢẸ́ OLÓGUN KAN TÍ WỌ́N ṢẸ̀ṢẸ̀ GBÀ SẸ́NU IṢẸ́ GÚN ỌLỌ́PÀÁ CONSTABLE KAN TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ AARON JOHN PA LÁSÌKÒ TÍ GBỌ́NMISI OMI Ò TO KAN BẸ́ SÍLẸ̀ LÁÀRÍN WỌN LÁAGO MẸ́SÀN-ÁN ỌJỌ́ AJÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ TÀRÁBÀ

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 5

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸFÀ OṢÙ KẸ́JỌ ỌDÚN 2025

1. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN ÌPÍNLẸ̀ MỌ́KÀNDÍNLÓGÚN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N ṢỌ́RA GIDIGIDI NÍTORÍ ÀRỌ̀Ọ̀RỌ̀DÁ ÒJÒ ỌLỌ́JỌ́ MÁRÙN-ÚN TÓ MÁA FA Ẹ̀KÚN OMI LÁWỌN AGBÈGBÈ MẸ́RÌNDÍNLỌ́GỌ́RIN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

2. ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÁNÒ TI ṢÀTÌLẸYÌN FÚN ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ GẸ́GẸ́ BÍ ỌMỌ ÒYE TÓ MÁA DÍJEDUPÒ ÀÀRẸ LẸ́KÀN-AN SI NÍNÚ ÌDÌBÒ ÀPAPỌ̀ TÓ MÁA WÁYÉ LỌ́DÚN 2027 BẸ́Ẹ̀ NÁÀ NI WỌ́N GBÓRÍYÌN FÚN Ọ̀MỌ̀WÉ ABDULLÁHÌ GANDUJE PÉ ADARÍ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) TÍ KÒ NÍ ẸLẸ́GBẸ́ NI

3. ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI SỌ PÉ ÀWỌN Ò ṢÀTÌLẸYÌN FÚN ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) ÀTI GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN ṢÁÁJÚ ÀTÚNDÌ ÌBÒ TÓ MÁA WÁYÉ NÍ ÌLÚ RẸ́MỌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, WỌ́N NÍ ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ LÀWỌN ṢÀTÌLẸYÌN FÚN GẸ́GẸ́ BÍ ỌMỌ ÒYE TÓ MÁA DÍJEDUPÒ ÀÀRẸ LẸ́KÀN-AN SI NÍNÚ ÌDÌBÒ ÀPAPỌ̀ TÓ MÁA WÁYÉ LỌ́DÚN 2027 NÍTORÍ KÍ AGBÁRA ṢÌ LÈ WÀ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÈNÌYÀN TÓ WÀ LÁPÁ GÚÚSÙ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

4. OLÓYÈ ÀGBÀ KAN NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) LÁPÁ ÀRÍWÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌYẸN ALWAN HASSAN TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀWỌN Ò NÍ ṢÀTÌLẸYÌN FÚN PETER OBI LÁTI DÍJEDUPÒ ÀÀRẸ LỌ́DÚN 2027 TORÍ PÉ Ó MÁA KÓ ÀWỌN OUN MÍMU ỌLỌ́TÍ WỌ APA ÀRÍWÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ LÁTI ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ

5. ÀJỌ ELÉTÒ ÌDÌBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (INEC) TI PÀṢẸ PÉ OLÓṢÈLÚ TÀBÍ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ KANKAN Ò GBỌ́DỌ̀ ṢE ÌPOLONGO ÈTÒ ÌDÌBÒ TÓ MÁA WÁYÉ LỌ́DÚN 2027 BÍ BẸ́Ẹ̀ KỌ́, ONÍTỌ̀HÚN Á FIMÚ KÁTA ÒFIN

6. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ IMỌ́, HOPE UZODINMA TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ GBOGBO ÀWỌN OLÓṢÈLÚ TÍ WỌ́N KÓRA WỌN JỌ KÀN Ń ṢE LÁSÁN NI TORÍ PÉ ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ MÁA LO ỌDÚN MẸ́JỌ GBÁKO GẸ́GẸ́ BÍ ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

7. ÀÀRẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, OLÓYÈ OLÚṢẸ́GUN ỌBÁSANJỌ́ TI RỌ ÀWỌN ADARÍ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ LÁTI MÁA ṢÀMÚLÒ ÒÒGÙN ÌBÍLẸ̀ LÁTI MÚ KÍ ÌTẸ̀SÍWÁJÚ Ó BÁ Ẹ̀KA ÈTÒ ÌLERA LỌ́NÀ ÌBÍLẸ̀

8. IKỌ̀ ÀMỌ̀TẸ́KÙN TI ṢÈLÉRÍ PÉ ÀWỌN MÁA TI BẸ̀RẸ̀ SI NÍ PÈSÈ ÈTÒ ÀÀBÒ TÓ NÍPỌN ṢÁÁJÚ AYẸYẸ Ọ̀ṢUN-ÒṢOGBO

9. ALÁBÒÓJÚTÓ FÚN ÈTÒ ÌGBÒKÈGBODÒ ỌKỌ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÁNÒ, ÀLHÁJÌ IBRAHIM NAMADI TI KỌ̀WÉ FIPÒ SÍLẸ̀ LẸ́YÌN Ẹ̀SÙN TÍ WỌ́N FI KÀN-ÁN PÉ Ó LỌ́WỌ́ SÍ GBÍGBA AFURASÍ OLÓÒGÙN OLÓRÓ KAN ÌYẸN SULAIMAN DANWAWU KALẸ̀

10. ADÁJỌ́ MỌ́BỌ́LÁJÍ TANÍMỌ̀LA TI ILÉ ẸJỌ́ GÍGA TÓ WÀ NÍ ỌGBÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI PÀṢẸ PÉ KÍ ỌKÙNRIN KÀN ẸNI ỌDÚN MẸ́RÌNLÉLÓGÓJÌ TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ WÀSÍÙ AKÍNWÁNDÉ TÍ GBOGBO ÈNÌYÀN MỌ̀ SÍ OLÓRÍ Ẹ̀ṢỌ́ Ó MÁA LỌ SÍ ỌGBÀ Ẹ̀WỌ̀N KIRÍKIRÌ LÁTARI Ẹ̀SÙN ÌPÀNÌYÀN O LỌ́KAN-Ò-JỌ̀KAN

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 7

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KÍNNÍ OṢÙ KẸ́JỌ ỌDÚN 2025

1. ÀWỌN GÓMÌNÀ TÓ WÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ MẸ́RÌNDÍNLÓGÓJÌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KỌMINÚ LÓRÍ ÀWỌN ÌPÈNIJÀ TÍ WỌ́N Ń KOJÚ LẸ́KA ÈTÒ Ẹ̀KỌ́

2. ÌGBÌMỌ̀ ÌṢÈJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ TI BỌWỌ́LU BÍLÍỌ́NÙ MÉJÌDÍNLÓGÚN ÀTI ÀÀBỌ̀ NÁÍRÀ (#18.5billion) FÚN ÀTÚNṢE OJÚ PÓPÓ, INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ ÀTÀWỌN IṢẸ́ ÀKÀNṢE MÌÍRÀN

3. ILÉ ẸJỌ́ KÒTẸ́MILỌ́RÙN TÓ FÌKÀLẸ̀ SÍ ÌLÚ ÀKÚRẸ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒǸDÓ TI FÌDÍ ÌJÁWÉ OLÚBORÍ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒǸDÓ, LUCKY AIYÉDÀTIWA ÀTI IGBÁKEJÌ Ẹ̀ Ọ̀MỌ̀WÉ ỌLÁYÍDÉ ADÉLÁMÌ MÚLẸ̀

4. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN TI ṢE ÌFILỌ́LẸ̀ GBỌ̀NGÁN ÌṢẸ̀M̀BÁYÉ OLÚMỌ TÍ WỌ́N ṢẸ̀ṢẸ̀ ṢE ÀTÚNṢE Ẹ̀, Ó SÌ KÉDE ÌWỌ́LÉ Ọ̀FẸ́ FÚN ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍTÍ DI ÌPARÍ OṢÙ KẸSÀN-ÁN ỌDÚN YÌÍ

5. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ, SÁNNÍ ÙBÁ TI YÀNNÀNÁ Ọ̀RỌ̀ PÉ ÒUN Ò FÚN ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ NÍ NÁÍRÀ KAN RÍ LÓJÚNÀ ÀTI JÀ FÚN ÌDÁJỌ́ ÒDODO ÀWỌN TÓ KÙ DÍẸ̀ KÁÀ TÓ FÚN

6. AṢOJÚ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TẸ́LẸ̀ NÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ UNITED KINGDOM AMBASSADOR TÚNJÍ ṢÀRÁFÀ ÌṢỌ̀LÁ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÒUN TI ṢETÁN LÁTI DÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN LỌ́DÚN 2027 BẸ́Ẹ̀ SÌ NI ÒUN SÌ TÍ Ń ṢIṢẸ́ LÓRÍ GBOGBO ÈRÓŃGBÀ ÀTI ÌLÀNÀ ÈTÒ ÌṢÈJỌBA ÒUN BÍ ÒUN BÁ DI GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN

7. ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ ÌBÒJÚ ÀÁNÚ WO NI LÁGBÀYÉ (AMNESTY INTERNATIONAL) TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ KÒ SÍ ÌDÁJỌ́ ÒDODO LẸ́YÌN ỌDÚN KAN PẸ̀LÚ BÍ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ ṢE NAWỌ́ GÁN ÀWỌN TÍ WỌ́N Ń ṢE ÌFẸ̀HỌ́NÚHÀN ALÁLÀÁFÍÀ

8. ÌDÀÀMÚ ỌKÀN BÁ ÀWỌN ALÁÌSÀN LÁWỌN ILÉ ÌWÒSÀN GBOGBO LÁTARI BÍ ÀWỌN OLÙTỌ́JÚ ALÁÌSÀN ÀTÀWỌN AGBẸ̀BÍ (NANNM) ṢE GÙNLÉ ÌYANṢẸ́LÓDÌ ONÍKÌLỌ̀ ỌLỌ́JỌ́ MẸ́Ẹ̀DÓGÚN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

9. ALÁKÒÓSO FÚN Ọ̀RỌ̀ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ LÁWỌN ÌPÍNLẸ̀, AMBASSADOR BIANCA ODUMEGWU-OJUKWU TI RAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ SÍ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA PÉ KÍ WỌ́N ṢE SÙÚRÙ LÓRÍ BÍ WỌ́N ṢE Ń FẸ̀HỌ́NÚHÀN TÍ WỌ́N SÌ Ń PÈ FÚN LÍLÉ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ KÚRÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ WỌN

10. ILÉ ẸJỌ́ ÌPÍNLẸ̀ KWARA TI DÁJỌ́ IKÚ FÚN ÀÁFÀ ÌLÚ ÌLỌRIN KÀN TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ ABDULRAHMAN BÉLLÒ PÉ KÍ WỌ́N LỌ YẸGI FUN LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ Ó ṢEKÚ PA Ọ̀RẸ́BÌNRIN Ẹ̀ TÓ PÀDÉ LÓRÍ Ẹ̀RỌ AYÉLUJÁRA FACEBOOK ÌYẸN HAFSOH YÉTÚNDÉ LAWAL ỌMỌ ỌDÚN MẸ́RÌNLÉLÓGÚN TÓ WÀ NÍ IPELE TÓ KẸ́YÌN NÍLÉ Ẹ̀KỌ́ OLÙKỌ́NI ÌPÍNLẸ̀ KWARA

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 8

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KỌKÀNLÉLỌ́GBỌ̀N OṢÙ KÉJE ỌDÚN 2025

1. ILÉ IṢẸ́ ELÉPO ILẸ̀ WA (NNPCL) TI SỌ PÉ ÀWỌN Ò TA ẸBU ÌFỌPO ILẸ̀ WA TÓ WÀ NÍ PORT HARCOURT, WỌ́N NÍ IRỌ́ ŃLÁ TÓ JÌNNÀ SÍ ÒTÍTỌ́ NI ÌRÒYÌN TÓ Ń JÀ RÀN-ÌN RÀN-ÌN KIRI

2. ÀWỌN OLÙTỌ́JÚ ALÁÌSÀN ÀTÀWỌN AGBẸ̀BÍ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NANNM) TI BẸ̀RẸ̀ ÌYANṢẸ́LÓDÌ ONÍKÌLỌ̀ ỌLỌ́JỌ́ MÉJE

3. ÌJỌBA ORÍLẸ̀ ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ TI SỌ KÒBÁKÙNGBÉ Ọ̀RỌ̀ SÍ ÀWỌN GÓMÌNÀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ WỌ́N MÁA Ń NÁ ÌNÁKÙNÁ FOWÓ ṢÒFÒ DÀNÙ LÓRÍ ÀWỌN ǸKAN TÍ KÒ WÚLÒ NI

4. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ BENUE, ÀLÙFÁÀ HYACINTH ALIA TI TÚ ÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ TÍ WỌ́N JỌ Ń ṢÈJỌBA KÁ LÉYÌÍ TÓ FI OLÓRÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ NÌKAN SÍLẸ̀

5. GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, ỌMỌBA DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN TI SỌ ÒGÚLÙTU Ọ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) TI DI KÒRÒFO LÁGBÀYÉ LÁTARI BÍ Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ WỌN ṢE Ń DIGBÁDAGBỌ̀N WỌN KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ

6. ẸNÌ KAN TÍ ÌRÈTÍ WÀ PÉ Ó FẸ́ DÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN LỌ́DÚN 2027, AMBASSADOR TÚNJÍ ṢÀRÁFÀ ÌṢỌ̀LÁ TI SỌ FÚN ÀWỌN TÍ WỌ́N Ń GBÌYÀNJÚ LÁTI DU IPÒ GÓMÌNÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN LỌ́DÚN 2027 PÉ WỌ́N GBỌ̀DỌ̀ MỌ ORÍSUN WỌN, IBI TÍ WỌ́N TI ṢẸ̀ WÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN KÍ WỌ́N TÓ BẸ̀RẸ̀ ÈTÒ ÌPOLONGO ÌBÒ GẸ́GẸ́ BÍ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN

7. ALÁKÒÓSO FÚN ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, Ọ̀MỌ̀WÉ TÚNJÍ ALÁÙSÁ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ WỌ́N MÁA BẸ̀RẸ̀ SI NÍ ṢE ÀYẸ̀WÒ ÒÒGÙN OLÓRÓ FÚN ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA GBOGBO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

8. ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI YAN ÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ ADARÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÀYÍKÁ ÀTI ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ TÓ WÀ NÍ KOROMA/SAAKPENWA ÒGÒNÌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS

9. OBÌNRIN AṢERUNLỌ́ṢỌ̀ KAN PÀDÁNÙ EYÍN MẸ́FÀ LẸ́NU Ẹ̀ LẸ́YÌN TÍ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ LÙ LÁLÙBAMI NÍ AGBÈGBÈ ÈBÚTÉ MẸ́TA NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ

10. ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA TI NAWỌ́ GÁN OBÌNRIN AFURASÍ ỌMỌ ỌDÚN MẸ́RÌNLÉLÓGÚN KAN TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ SOMTOCHUKWU NWAFOR LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ Ó ṢEKÚ PA ALÁBOYÚN KAN TÓ JẸ́ OLÙTỌ́JÚ ALÁÌSÀN, TÓ SÌ GÉ Ẹ̀YÀ ARA RẸ̀ TÀ FÚN BABALÁWO

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 7

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌGBỌ̀N ỌJỌ́ OṢÙ KÉJE ỌDÚN 2025

1. ALÁKÒÓSO FÚN ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, Ọ̀MỌ̀WÉ TÚNJÍ ALÁÙSÁ TI SỌ̀RỌ̀ SÍTA PÉ ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AṢÍWÁJÚ BỌ́LÁ AHMED TINÚBÚ GBA ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ KÚRÒ NÍNÚ OKO GBÈSÈ NI KÌÍ ṢE PÉ Ó Ń NIWÁ LÁRA BÍ ÀWỌN KÀN ṢE Ń SỌ KIRI

2. OBÌNRIN ÀKỌ́KỌ́ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TÍ Ó TÚN JẸ́ AYA ÀÀRẸ ÌYẸN AṢÒFIN OLÚRẸ̀MÍ TINÚBÚ TI FÚN ÀWỌN TÍ ÀWỌN AGBÉBỌN ṢE ÌKỌLÙ SÍ NÍ YELEWATA NÍ ÌPÍNLẸ̀ BÉNÚÈ NÍ OWÓ TÓ TÓ BÍLÍỌ́NÙ KAN NÁÍRÀ KÍ WỌ́N LÈ BẸ̀RẸ̀ SI NÍ GBÉ ÌGBÉ AYÉ Ọ̀TUN

3. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TI RỌ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TÍ WỌ́N Ń ṢE ÀTÌPÓ NÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA PÉ KÍ WỌ́N ṢE SÙÚRÙ GIDIGIDI LÁTARI BÍ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA ṢE Ń FẸ̀HỌ́NÚHÀN PÉ KÍ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ó KÚRÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA NÍTORÍ ÀWỌN Ẹ̀SÙN ÌWÀ Ọ̀DARÀN TÍ WỌ́N FI KÀN WỌ́N

4. AKỌ̀WÉ FÚN ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AṢÒFIN GEORGE AKUME TI RỌ ÀWỌN OLÓṢÈLÚ LÁTI APÁ ÀRÍWÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ PÉ KÍ WỌ́N DÚRÓ DI ỌDÚN 2031 KÍ WỌ́N TÓ LÈ GBÉ ÌGBÉSẸ̀ ÀTI DÍJEDUPÒ ÀÀRẸ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

5. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ GBÍGBA ÀWỌN ỌMỌBÌNRIN ILÉ Ẹ̀KỌ́ GOVERNMENT GIRLS SECONDARY SCHOOL TÓ WÀ NÍ CHIBOK NÍ ÌPÍNLẸ̀ BORNO ÀTI LEAH SHARIBU LỌ́WỌ́ ÀWỌN TÍ WỌ́N JÍ WỌN GBÉ JẸ́ OUN TÓ MU ỌMÚ LÁYÀ ÀWỌN TORÍ PÉ ÀWỌN TI Ń GBÌYÀNJÚ LÁBẸ́LẸ̀ LÁTI GBA ÀWỌN ỌMỌ NÁÀ KALẸ̀ LÁÌPẸ́ LÁÌJÌNNÀ

6. ADÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN LÁBẸ́ ÀSÍÁ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY LỌ́DÚN 2023, HON. LÁDI ADÉBUTÚ TI PÀDÁNÙ ÀWỌN ALÁTÌLẸYÌN Ẹ̀ MÉJÌ ÌYẸN HON. SÍKÍRÙLÁHÌ ÒGÚNDÉLÉ ÀTI HON. KÚNLÉ AKÍNLÀDÉ SÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) LÁTARI BÍ ÀWỌN MÉJÈÈJÌ YÌÍ ṢE DIGBÁDAGBỌ̀N WỌN KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) LỌ SÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC)

7. GÓMÌNÀ TẸ́LẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN, ỌMỌBA ỌLÁGÚNSÓYÈ OYINLỌLÁ TI SỌ ÒGÚLÙTU Ọ̀RỌ̀ SÍ ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ PÉ ÌṢÈJỌBA RẸ̀ MÚ ÌJÌYÀ ÀTI ÌRORA Ọ̀TUN BÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ KÌÍ ṢE ÌRÈTÍ Ọ̀TUN TÓ ṢÈLÉRÍ Ẹ̀ LÁSÌKÒ TÓ Ń POLONGO ÌBÒ

8. ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ MÍ MÁA FI ÒFIN DE GBÍGBÉ TÀBÍ MÍ MÁA LO ÒÒGÙN OLÓRÓ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NDLEA) TI TA ÀWỌN ILÉ MÉJÌ NÍNÚ MẸ́JỌ TÍ Ó JẸ́ ÀWỌN ǸKAN ÌNÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN KAN TÍ WỌ́N NAWỌ́ GÁN PÉ WỌ́N Ń ṢE FÀYÀWỌ́ ÒÒGÙN OLÓRÓ ÀTI ÀWỌN ÌWÀ ÌBÀJẸ́ TÓ FARAPẸ NÍ OWÓ TÓ TÓ MÍLÍỌ́NÙ MỌ́KÀNDÍNLÓGÓJE NÁÍRÀ NÍ OLÚ ILÉ IṢẸ́ WỌN TÓ WÀ NÍ ÀBÚJÁ

9. ALÁGA ÌGBÌMỌ̀ ÀTÙNTÓ ÀTI OLÙPARÍ ÌJÀ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) BÙKỌ́LÁ SÀRÀKÍ TI SỌ PÉ ÒUN Ò NÍ KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) BẸ́Ẹ̀ SÌ NI ÒUN Ò PÀṢẸ FÚN ÀWỌN ALÁTÌLẸYÌN ÒUN LÁTI DARA PỌ̀ MỌ́ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ AFRICAN DEMOCRATIC CONGRESS(ADC)

10. ÀWỌN OLÙGBÉ ABÚLÉ ÌTAṢÌN NÍ ÌMOBÌ Ọ̀GBẸ̀RẸ̀ NÍ ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ ÌLÀ OÒRÙN ÌJẸ̀BÚ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI Ń DÚNKOKÒ PÉ ÀWỌN MÁA ṢÀWÁRÍ ERIN TÓ ṢEKÚ PA ÀGBẸ̀ KAN TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ YÀYÁ KÁLÀMÙ NÍNÚ OKO, TÍ ÀWỌN ṢÌ MÁA PA ÀWỌN EERIN TÍ ÀWỌN BÁ FOJÚ KÀN

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 4

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸTÀDÍNLỌ́GBỌ̀N OṢÙ KÉJE ỌDÚN 2025

1. ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ MÁA FÚN ÀWỌN AGÙNBÁNIRỌ̀ TÍ WỌ́N TÓ OKÒÓÓLÉNÍGBA Ó DÍN MẸ́WÀÁ TÍ WỌ́N PEREGEDÉ JÙLỌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ NÍ ÀÀMÌ Ẹ̀YẸ ÌDÁLỌ́LÁ

2. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI BỌWỌ́LU OWÓ TÓ TÓ ẸGBẸ̀RÚN LỌ́NÀ Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀RIN NÁÍRÀ GẸ́GẸ́ BÍ OWÓ TÓ KÉRÉ JÙ LÁTI MÁA RA ÀWỌN ǸKAN PẸ́PẸ̀Ẹ̀PẸ́ LÁWỌN Ọ́FÌSÌ ÀWỌN ALÁKÒÓSO LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

3. ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ TI KÌLỌ̀ FÚN GÓMÌNÀ TẸ́LẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ, AYỌ̀DÉLÉ FÁYỌ̀ṢE PÉ KÓ FI ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ SÍLẸ̀, WỌ́N NÍ Ọ̀DÀLẸ̀ NI

4. ÀWỌN AṢÒFIN ÀGBÀ TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN GÓMÌNÀ LÓRÍ BÍ WỌN Ò ṢE JẸ́ KÍ ÀWỌN ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ Ó DÁ DÚRÓ FÚN RA WỌN

5. ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ AFRICAN DEMOCRATIC CONGRESS (ADC) TI ṢÈLÉRÍ PÉ ÀWỌN MÁA NA TÁN BÍ OWÓ PẸ̀LÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) NÍNÚ ÌDÌBÒ ÀPAPỌ̀ TÓ MÁA WÁYÉ LỌ́DÚN 2027 LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

6. GARBA SHEHU TÍÍ ṢE AGBẸNUSỌ TẸ́LẸ̀ FÚN ÀÀRẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TÓ DI OLÓÒGBÉ, AJAGUNFẸ̀YÌNTÌ MÙHÁMMÁDÙ BÙHÁRÍ TI SỌ̀RỌ̀ SÍ FẸ́MI ADÉṢÍNÀ PÉ KÒ YẸ KÓ JẸ́ ÒUN LÓ MA MÁA BU ẸNU ÀTẸ́ LU BÍ Ẹ̀KA ÈTÒ ÌLERA ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢE RÍ LÁTARI PÉ BÙHÁRÍ LỌ Ń GBA ÌTỌ́JÚ LÓKÈ ÒKUN LÁWỌN ÀSÌKÒ TÍ ARA RẸ̀ KÒ YÁ KÓ TÓ DI OLÓÒGBÉ

7. GÓMÌNÀ TẸ́LẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN, ADÉGBÓYÈGA OYÈTỌ́LÁ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÒUN Ò NI LỌ́KÀN LÁTI TÚN DÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN

8. ILÉ IṢẸ́ ẸBU ÌFỌPO DANGOTE TÍ KÓ ÀWỌN ỌKỌ̀ ÀJÀGBÉ EPO TÓ TÓ ẸGBẸ̀RÚN MẸ́RIN TÍ YÓÒ MÁA LO AFẸ́FẸ́ GÁÀSÌ WỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ LÁTI FI MÁA GBÉ EPO KÁÀKIRI ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ

9. AṢÒFIN ÀGBÀ ABÍỌ́DÚN OLÚJÌMÍ TI DIGBÁDAGBỌ̀N Ẹ̀ KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) LỌ SÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ

10. ÀJỌ TÓ Ń BÓJÚTÓ ÀWỌN AGÙNBÁNIRỌ̀ (NYSC) Ẹ̀KA TI ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ TI KÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN AGÙNBÁNIRỌ̀ TÍ WỌ́N Ń SÌNRÚ ÌLÚ NÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ PÀÁPÀÁ JÙ LỌ ÀWỌN OBÌNRIN PÉ KÍ WỌ́N ṢỌ́RA GIDIGIDI NÍPA ỌDÚN EGÚNGÚN TÓ MÁA BẸ̀RẸ̀ NÍ ÌLÚ ÌBÀDÀN LỌ́JỌ́ AJÉ TÓ Ń BỌ̀

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 11

YORUBA BROADCASTING NETWORK (YBN)

ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KARÙNDÍNLỌ́GBỌ̀N OṢÙ KÉJE ỌDÚN 2025

1. ALÁGA TUNTUN TÍ WỌ́N ṢẸ̀ṢẸ̀ YAN FÚN ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC), Ọ̀JỌ̀GBỌ́N NENTAWE YILTWADA TÍ ṢÈLÉRÍ PÉ ÌṢỌ̀KAN ÀTI ÌMÚGBÒÒRÒ MÁA DÉBÁ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ GẸ́GẸ́ BÍ ÒUN ṢE DI ALÁGA ẸGBẸ́ NÁÀ

2. ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) TI YAN ÌLÚ ÌBÀDÀN TÍÍ ṢE OLÚ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ GẸ́GẸ́ BÍ IBI TÍ WỌ́N TI MÁA ṢE ÌPÀGỌ́ ÀPAPỌ̀ WỌN TÓ MÁA WÁYÉ LÓṢÙ KỌKÀNLÁ ỌDÚN YÌÍ

3. ÀJỌ ELÉTÒ ÌDÌBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (INEC) TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÀWỌN TI GBA ÀWỌN ÌWÉ KAN TÓ Ń BÉÈRÈ FÚN ÌFORÚKỌSÍLẸ̀ ÀWỌN ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ MẸ́WÀÁ TUNTUN MÍÍRAN ṢÁÁJÚ ÈTÒ ÌDÌBÒ ỌDÚN 2027

4. ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI TÚN GBA ÀWỌN IKỌ̀ ELÉTÒ ÀÀBÒ ÀMỌ̀TẸ́KÙN TÓ TÓ Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀TA ÀTI ÀÁDỌ́TA MỌ́ ÀWỌN TÍ Ó TI WÀ NÍLẸ̀ TẸ́LẸ̀ LÁTI LÈ JẸ́ KÍ ÈTÒ ÀÀBÒ Ó TÚN RINLẸ̀ SI NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN

5. ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń RÍ SÍ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ TI ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TI GBÉ ÒFIN KAN KALẸ̀ FÁWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍRÁMÀ TÍ KÌÍ ṢE TI ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀, ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÀTI ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ PÉ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TÓ BÁ FẸ́ WỌ IPELE KÍNNÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GIRAMA YÌÍ GBỌ́DỌ̀ JẸ́ ỌMỌ ỌDÚN MÉJÌLÁ

6. ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI SANWÓ ILÉ ÌWÒSÀN ỌMỌ OBÌNRIN KÉKERÉ KAN TÓ LỌ LÓYÚN LÁSÌKÒ TÓ Ń GBARADÌ FÚN ÌDÁNWÒ ÀṢEKÁGBÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍRÁMÀ ÌYẸN TÈMILỌLÁ ADÉDÌRAN LÉYÌÍ TÍ ẸNI TÓ FÚN LÓYÚN SÁ LỌ LÁTARI PÉ Ó BÍ ÌBẸTA ỌMỌ SÍ ILÉ ÌWÒSÀN SACRED HEART HOSPITAL TÓ WÀ NÍ LÁǸTÓRÓ NÍLÙÚ ABẸ́ÒKÚTA

7. ÀJỌ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ MÍ MÁA ṢE FÀYÀWỌ́ ÀWỌN ÈNÌYÀN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NAPTIP) TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA LÓRÍ BÍ MÍ MÁA ṢE FÀYÀWỌ́ ÀWỌN ÈNÌYÀN KÚRÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LỌ SÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ GHANA ÀTI ÀṢÀ MÍ MÁA YỌ ÀWỌN Ẹ̀YÀ ARA ÈNÌYÀN ṢE Ń RÚ GỌ́GỌ́ SI LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ YÌÍ

8. ILÉ ẸJỌ́ GÍGA TÓ FÌKÀLẸ̀ SÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI PÀṢẸ FÚN ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N LỌ SAN MÍLÍỌ́NÙ MẸ́WÀÁ NÁÍRÀ GẸ́GẸ́ BÍ OWÓ GBÀ MÁBINÚ LÁTARI BÍ WỌ́N ṢE NAWỌ́ GÁN ÀWỌN TÍ WỌ́N Ń ṢE ÈTÒ ÌFẸ̀HỌ́NÚHÀN ALÁLÀÁFÍÀ LÁTI FI ṢE ÌRÁNTÍ ỌDÚN KẸRÌN TÍ WỌ́N PÀDÁNÙ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ KAN LÁSÌKÒ ÈTÒ ÌFẸ̀HỌ́NÚHÀN FÍFI ÒPIN SÍ ỌLỌ́PÀÁ KÒBÓLÈRẸ́ TÓ WÁYÉ NÍ ÌLORO LEKKI LỌ́DÚN 2020

9. GÓMÌNÀ TẸ́LẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA TÍ Ó TÚN JẸ́ ADÍJEDUPÒ ÀÀRẸ LÁBẸ́ ÀSÍÁ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY LỌ́DÚN 2023, PETER OBI TI SỌ PÉ ÒUN ṢÌ MÁA PADÀ LỌ SÍ ÌPÍNLẸ̀ EDO TORÍ PÉ ÌDÚNKOKÒ MONDAY OKPEBHOLO TÍÍ ṢE GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ Ò LÈ MÚ KÍ ÒUN MÁ LỌ SÍ ÌPÍNLẸ̀ NÁÀ

10. ỌKÙNRIN KAN TÍ ORÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ CHIEMELIE OBORJI ṢEKÚ PA ALÁBOYÚN KAN TÓ JẸ́ OLÙTỌ́JÚ ALÁÌSÀN LẸ́YÌN TÓ PARỌ́ FÚN PÉ KÓ WÁ BÁ ÒUN TỌ́JÚ ÌYÁ ÒUN TÓ Ń ṢE ÀÌSÀN NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA LÉYÌÍ TÓ SÌ TI SÁLỌ LẸ́YÌN TÓ ṢE IṢẸ́ LÁABI YÌÍ TÁN

ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń DC ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́

6 months ago | [YT] | 5